Ṣé'bẹ̀ lẹ ma sùn (Ṣé'bẹ̀ lẹ ma)
[9ice]
Ọjọ́ re bí àná ta gb'òmìnira 1960
N'ígbà yen, things easy gẹ́gẹ́ b'ọ́n ṣe wí
T'arúgbó, t'omidan ló ń dunú p'ati gb'òmìnira
Omi ìnira, indeed àbí, ẹ wo Náírà wa
Ìlú polúkúrúmuṣu, t'èwe t'àgbà lọ́ ń j'eyán wọn níṣu
Àbẹ́ òri? Èwe ẹri, ṣùgbọ́n ẹ ò fẹ́wí
Àbẹ́ òri? Àgbà ẹri àtẹnujẹ l'ófẹ́ p'ayín
Pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ ta ná ní p'ọ̀pá, ẹní bátabà, k'ólọ mọ fẹ ni
[Chorus, 9ice]
Ṣé'bẹ̀ lẹ ma sùn
T'ẹbá sọpé ẹ ò mọ ǹkankan
Ẹ̀yìn ààrò l'ẹma wà (Ṣé'bẹ̀ lẹ ma)
Mẹ́wa ń ṣẹlẹ̀ o
Ṣé'bẹ̀ lẹ ma sùn (Ṣé'bẹ̀ lẹ ma sùn)
Bí ẹní wò'ṣẹ́jú akàn o
Ẹ̀yìn ààrò l'ẹma wà a
Mẹ́wa ń ṣẹlẹ̀ o
[Asa]
Kíni sùúrù tí ò l'érè?
Kíni iṣẹ́ tí kò s'érè?
Wọ́n ṣà l'éyàn tí ò l'órúkọ
Ó kúkú ṣiṣẹ́, ó dẹ̀'ń r'érè e
Ah! Ẹ dẹ̀ sọpé aṣìwà l'ọ́mọdé
Ǹkan ṣá l'ẹyẹ ń jẹ k'ágbàdo tó dé
9ice ọ̀rọ̀ gidi lo sọ
Ọ̀rọ̀ tó nílárí lo sọ
A'láti fi làákàyè si
K'a sọ̀rọ̀ síbi t'ọ́rọ̀ wà
[Chorus, Asa]
Ṣé'bẹ̀ lẹ ma sùn o (Ṣé'bẹ̀ lẹ ma sùn)
Ẹ̀yìn ààrò l'ẹma wà a (Ṣé'bẹ̀ lẹ ma sùn)
Mẹ́wa ń ṣẹlẹ̀ o
Ṣé'bẹ̀ lẹ ma sùn o (Ẹ̀yìn ààrò, ẹ̀yìn ààrò l'ẹma wà)
T'ẹbá wò'ṣẹ́jú akàn o
Ẹ̀yìn ààrò l'ẹma wà o
Mẹ́wa ń ṣẹlẹ̀ o
[9ice]
Bó d'àsìkò ìbò yen, wọ́n á wá s'àdúgbò
Wọ́n a ṣ'ọmọ jẹ́jẹ́
Ẹ jẹ́ kón wọlé tán, gbogbo ẹ̀jẹ́ tán jẹ́ láwọ́ kẹ iṣẹ́
T'óbá tún ṣe wẹ́rẹ́, lásìkò ìbò, wọ́n á ní k'ọ̀dọ́ tò lọ bẹrẹ
Wọ́n á ṣ'ẹnu mẹ́rẹ́, kàlòkàlò gbé ǹkan mì ṣ'ẹnu wúyẹ́
Atilabú tún ti wọlé, taló dìbò fun?
Pàsán ta fi nà'yálé, ó ń bẹ lórí àjà fun
Ọ̀dọ́ ẹ lo túnramú
Ẹ má jẹ'an p'àgbọ́n ní funfun... fún yín
Mowí tèmi
[Asa]
Àṣegbé kan ò sí ó
Àṣepamó ló wà (bẹ́ẹ̀ni, bẹ́ẹ̀ni)
Àṣe sílẹ̀ l'àbọ̀wábá
Èmi ò tíì kú, mo ṣìle ṣ'iṣẹ́
Mo ṣìle f'ọwọ́ wẹ'wọ́
Mo ṣìle tún'lé mi ṣe
[Chorus, 9ice]
Ṣé'bẹ̀ lẹ ma sùn
T'ẹbá sọpé ẹ ò mọ ǹkankan
Ẹ̀yìn ààrò l'ẹma wà
Mẹ́wa ń ṣẹlẹ̀ o
Ṣé'bẹ̀ lẹ ma sùn (Ṣé'bẹ̀ lẹ ma sùn)
Bí ẹní wò'ṣẹ́jú akàn o
Ẹ̀yìn ààrò l'ẹma wà a (Ṣé'bẹ̀ lẹ ma)
Mẹ́wa ń ṣẹlẹ̀ o
[Outro]
Ooh oh oh oh yeah yeah yeah
Yeah yeah yeah oh